Skip to content
1 Tẹsalonika 5:1-11

1 Tẹsalonika 5:1-11

1
Nísinsin yìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà,
2
nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru.
3
Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.
4
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè.
5
Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́.
6
Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́.
7
Nítorí àwọn tí wọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru.
8
Ṣùgbọ́n àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí ìgbàyà ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí àṣíborí.
9
Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jesu Kristi.
10
Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀.
11
Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options