1 Samuẹli 28:3-10
3
Samuẹli sì ti kú, gbogbo Israẹli sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rama ní ìlú rẹ̀. Saulu sì ti mú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.
4
Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa.
5
Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.
6
Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì.
7
Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.”
8
Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”
9
Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”
10
Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings