1 Samuẹli 26:14-25
14
Dafidi sì kọ sí àwọn ènìyàn náà àti sí Abneri ọmọ Neri wí pé, “Ìwọ kò dáhùn, Abneri?” Nígbà náà ni Abneri sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ta ni ń pe ọba?”
15
Dafidi sì wí fún Abneri pé, “Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí? Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Israẹli? Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ? Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba olúwa rẹ.
16
Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí Olúwa ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni àmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà níbi tìmùtìmù rẹ̀.”
17
Saulu sì mọ ohùn Dafidi, ó sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí Dafidi ọmọ mi?” Dafidi sì wí pé, “Ohùn mi ni, olúwa mi, ọba.”
18
Òun sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀? Kín ni èmi ṣe? Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi.
19
Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe Olúwa bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú Olúwa; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má ba à ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní Olúwa, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’
20
Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”
21
Saulu sì wí pé, “Èmi ti dẹ́ṣẹ̀: yípadà, Dafidi ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe iyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.”
22
Dafidi sì dáhùn, ó sì wí pé, “Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á.
23
Kí Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa.
24
Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú Olúwa, kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo.”
25
Saulu sì wí fún Dafidi pé, “Alábùkún fún ni ìwọ, Dafidi ọmọ mi: nítòótọ́ ìwọ yóò sì ṣe nǹkan ńlá, nítòótọ́ ìwọ yóò sì borí.” Dafidi sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Saulu sì yípadà sí ibùgbé rẹ̀.
Settings