Skip to content
1 Samuẹli 23:1-13

1 Samuẹli 23:1-13

1
Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.”
2
Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?” Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.”
3
Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhìn-ín yìí ní Juda; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Keila láti fi ojú ko ogun àwọn ara Filistini?”
4
Dafidi sì tún béèrè lọ́dọ̀ Olúwa. Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Filistini náà lé ọ lọ́wọ́.”
5
Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Keila, wọ́n sì bá àwọn ará Filistini jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dafidi sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀.
6
Ó sì ṣe, nígbà tí Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú efodu kan lọ́wọ́ rẹ̀.
7
A sì sọ fún Saulu pé Dafidi wá sí Keila. Saulu sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.”
8
Saulu sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, láti ká Dafidi mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.
9
Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín yìí!”
10
Dafidi sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi.
11
Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Saulu yóò ha sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”
12
Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”
13
Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta (600) ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options