1 Samuẹli 17:45-58
45
Dafidi sì wí fún Filistini pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí ìwọ tí gàn.
46
Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli.
47
Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ wa.”
48
Bí Filistini ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀. Dafidi yára sáré sí òun náà láti pàdé e rẹ̀.
49
Dafidi ti ọwọ́ sí àpò rẹ̀, ó sì mú òkúta jáde wá ó sì fì í, ó sì jù ú sí ọ̀kọ́kán iwájú orí Filistini. Òkúta náà sì wọ̀ ọ́ níwájú orí, ó sì ṣubú ó sì dojúbolẹ̀ ní orí ilẹ̀.
50
Dafidi yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistini pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, láìsí idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó lu Filistini, ó sì pa á.
51
Dafidi sì sáré ó sì dúró lórí rẹ̀. Ó sì mú idà Filistini, ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ ọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa á tan, ó sì gé orí rẹ̀ pẹ̀lú idà. Nígbà tí àwọn ará Filistini rí i wí pé akọni wọn ti kú, wọ́n yípadà wọ́n sì sálọ.
52
Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Israẹli àti ti Juda súnmọ́ iwájú pẹ̀lú ariwo, wọ́n sì lépa àwọn ará Filistini dé ẹnu ibodè Gati àti títí dé ẹnu ibodè Ekroni. Àwọn tí ó kú wà káàkiri ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà Ṣaaraimu àti títí dé ọ̀nà Gati àti Ekroni.
53
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli sì padà láti máa lé àwọn ará Filistini, wọ́n sì ba ibùdó wọn jẹ́.
54
Dafidi gé orí Filistini ó sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ohun ìjà Filistini sínú àgọ́ tirẹ̀.
55
Bí Saulu sì ti wo Dafidi bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Filistini, ó wí fún Abneri, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Abneri, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?” Abneri dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.”
56
Ọba sì wí pé, “Wádìí ọmọ ẹni tí ọmọdékùnrin náà ń ṣe.”
57
Kété tí ó dé láti ibi tí ó ti lọ pa Filistini, Abneri sì mú u wá síwájú Saulu, orí Filistini sì wà ní ọwọ́ Dafidi.
58
Saulu béèrè pé, “Ọmọdékùnrin, ọmọ ta ni ọ́?” Dafidi dáhùn pé, “Èmi ni ọmọ ìránṣẹ́ rẹ Jese ti Bẹtilẹhẹmu.”
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings