1 Ọba 20:21-34
21
Ọba Israẹli sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Aramu ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
22
Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Israẹli, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Aramu yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”
23
Àwọn ìránṣẹ́ ọba Aramu sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú.
24
Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe, mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi baálẹ̀ sí ipò wọn.
25
Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Israẹli jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba tiwọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.
26
Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Beni-Hadadi ka iye àwọn ará Aramu, ó sì gòkè lọ sí Afeki, láti bá Israẹli jagun.
27
Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Israẹli sì dó ní òdìkejì wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Aramu kún ilẹ̀ náà.
28
Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Israẹli pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Aramu rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”
29
Wọ́n sì dó sí òdìkejì ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Israẹli sì pa ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú àwọn ará Aramu ní ọjọ́ kan.
30
Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Afeki, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàá mẹ́tàlá lé ẹgbẹ̀rún (27,000) nínú wọn. Beni-Hadadi sì sálọ sínú ìlú, ó sì fi ara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.
31
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.”
32
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Israẹli wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Beni-Hadadi wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí èmi kí ó yè.’ ” Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láààyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”
33
Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Beni-Hadadi arákùnrin rẹ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Beni-Hadadi jáde tọ̀ ọ́ wá, Ahabu sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.
34
Beni-Hadadi sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Damasku, bí baba mi ti ṣe ní Samaria.” Ahabu sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.
Settings