Skip to content
1 Ọba 20:1-12

1 Ọba 20:1-12

1
Beni-Hadadi ọba Aramu sì gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ. Ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó sì gòkè lọ, ó sì dó ti Samaria, ó sì kọlù ú.
2
Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí ìlú sí Ahabu ọba Israẹli wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi wí,
3
‘Fàdákà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.’ ”
4
Ọba Israẹli sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí olúwa mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ ni.”
5
Àwọn oníṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Beni-Hadadi sọ wí pé, ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ.
6
Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”
7
Nígbà náà ni ọba Israẹli pe gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”
8
Àwọn àgbàgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má ṣe fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí ó gbà fún un.”
9
Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Beni-Hadadi pé, “Sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Beni-Hadadi.
10
Beni-Hadadi sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Ahabu wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eruku Samaria yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”
11
Ọba Israẹli sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé, ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́ra halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ”
12
Beni-Hadadi sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ ṣígun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options