Skip to content
1 Kronika 12:23-40

1 Kronika 12:23-40

23
Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni láti yí ìjọba Dafidi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
24
Ọkùnrin Juda, tí o ń gbé asà àti ọ̀kọ̀, ẹgbàáta lé lẹ́gbẹ̀rin (6,800) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun.
25
Àwọn ọkùnrin Simeoni, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó lé ọgọ́rùn-ún (7,100);
26
àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600),
27
pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (3,700) ènìyàn,
28
àti Sadoku akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀;
29
àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà;
30
àwọn arákùnrin Efraimu, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ogún ẹgbẹ̀rún ó le ẹgbẹ̀rin (20,800);
31
àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000).
32
Àti ní ti àwọn ọmọ Isakari, àwọn ẹni tí ó ní òye àkókò, láti mọ ohun tí Israẹli ìbá máa ṣe; olórí wọn jẹ́ ìgbà; àti gbogbo àwọn ìbátan wọn ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn.
33
Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000).
34
Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000). Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn.
35
Àwọn ọkùnrin Dani, tí wọ́n ṣetán fún ogun ẹgbàá mẹ́tàlá (28,600).
36
Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì (40,000).
37
Láti ìlà-oòrùn Jordani, ọkùnrin Reubeni, Gadi, àti ìdajì ẹ̀yà Manase, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000).
38
Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ́ fún nínú ẹgbẹ́. Wọ́n wá sí Hebroni tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dafidi jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Israẹli sì jẹ́ onínú kan láti fi Dafidi jẹ ọba.
39
Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dafidi, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèsè oúnjẹ fún wọn.
40
Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options