Fò sí àkóónú

Hosea6

Ẹ Jẹ́ Ká Padà Sí OLÚWA

1
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
2
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀.
3
Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa; ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, yóò jáde; yóò tọ̀ wá wá bí òjò, bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

Ọlọ́run Kẹ́dùn Nítorí Ìdúróṣinṣin Àkókò Kúkúrú

4
“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
5
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín.
6
Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

Àdàkàdé àti Ìbàjẹ́ Dẹ́bi

7
Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
8
Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.
9
Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.
10
Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù ní ilé Israẹli. Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè Israẹli sì di aláìmọ́.
11
“Àti fún ìwọ, Juda, a ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ. “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options