Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Year: Satan to be bound a thousand years

4 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Satan to be bound a thousand years

  1. O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

  2. Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà yóò fi pé. Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

  3. Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n, mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

  4. Nígbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀.