Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Worldly Care: General references

15 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. “Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?

  2. Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?

  3. Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?

  4. “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú.

  5. Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí.

  6. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?

  7. Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’

  8. Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí.

  9. Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú.

  10. Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.

  11. “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

  12. “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

  13. “Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’

  14. Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn.

  15. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn,