Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Urim and Thummin: Illustrative of the light and perfection of Christ, the true high priest
Àwọn ẹsẹ nípa Illustrative of the light and perfection of Christ, the true high priest
Ní ti Lefi ó wí pé, “Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ. Ẹni tí ó dánwò ní Massa, ìwọ bá jà ní omi Meriba.
Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé,
Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé.
Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.
Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìṣúra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí.