Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Total Abstinence

18 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Olúwa sì sọ fún Aaroni pé.

  2. “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkígbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kù ú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran.

  3. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín mímọ́ àti àìmọ́, láàrín èérí àti àìléèérí.

  4. irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ.

  5. Níwọ́n ìgbà tí ó sì jẹ́ Nasiri, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èso àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀.

  6. Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan,

  7. Angẹli Olúwa náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un

  8. kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.”

  9. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ.

  10. Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí; àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;

  11. Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

  12. Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

  13. “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli, kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì, kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,

  14. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jonadabu ọmọ Rekabu, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé.

  15. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’

  16. Báyìí ni àwa gba ohùn Jehonadabu ọmọ Rekabu baba wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó pàṣẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa.

  17. ‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.

  18. Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá.