Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tiglath-Pileser: Forms an alliance with Ahaz; captures Damascus
Àwọn ẹsẹ nípa Forms an alliance with Ahaz; captures Damascus
Ahasi sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tiglat-Pileseri ọba Asiria wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Siria, àti lọ́wọ́ ọba Israẹli tí ó dìde sí mi.”
Ahasi sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúra ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Asiria ní ọrẹ.
Ọba Asiria sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba Asiria gòkè wá sí Damasku, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí Kiri, ó sì pa Resini.
Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.
Olúwa sì rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi ọba Israẹli, nítorí ó sọ Juda di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì ṣe ìrékọjá gidigidi sí Olúwa.
Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.
Ahasi mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Asiria: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.