Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Threshing

58 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú,

  2. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú Olúwa; bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.

  3. “Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.

  4. Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.

  5. Ẹni ti àmúga ìpakà rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó alikama rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”

  6. Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi?

  7. Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè.

  8. Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.”