Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Sun: (Darkened,) of severe calamities
Àwọn ẹsẹ nípa (Darkened,) of severe calamities
Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn; èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
Ayé yóò mì níwájú wọn; àwọn ọ̀run yóò wárìrì; oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.
A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.
“Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’
Ó sì ṣí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn àti ojú sánmọ̀ sì ṣókùnkùn nítorí èéfín ihò náà.