Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Stars: Appointed to give light by night

4 ẹsẹ · 40 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Appointed to give light by night

  1. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.

  2. Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú.

  3. Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  4. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru; tí ó rú omi Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.