Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Roman Empire: Crowning of conquerors
Àwọn ẹsẹ nípa Crowning of conquerors
Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé.
Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu.
Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.