Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Promises of God: Christ

6 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Christ

  1. Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀.

  2. Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé.

  3. Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’

  4. “Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

  5. Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣọ wí pé, “fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀,” bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, “àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kristi.

  6. Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá.