Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Mule

17 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Àwọn ọmọ Sibeoni: Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀.

  2. “ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.

  3. Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.

  4. Absalomu sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. Absalomu sì gun orí ìbáaka kan, ìbáaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbáaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò.

  5. ọba sì wí fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa yín pẹ̀lú yín kí ẹ sì mú kí Solomoni ọmọ mi kí ó gun ìbáaka mi, kí ẹ sì mú un sọ̀kalẹ̀ wá sí Gihoni.

  6. Wọ́n tún máa ń mú ọkà barle àti koríko fún ẹṣin àti fún ẹṣin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀.

  7. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún olúkúlùkù àwọn tí ń wá sì ń mú ẹ̀bùn tirẹ̀ wá, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò wúrà àti ẹ̀wù, àti tùràrí olóòórùn dídùn, ẹṣin àti ìbáaka.

  8. Ahabu sì ti wí fún Obadiah pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹṣin àti àwọn ìbáaka là, kí a má bá à ṣòfò àwọn ẹranko pátápátá.”

  9. Naamani wí pé, “Tí o kò bá nígbà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí a fi fún èmi ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ẹrù erùpẹ̀ tí ìbáaka méjì le rù, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rú ẹbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn mọ́ bí kò ṣe sí Olúwa.

  10. Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.

  11. Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin ẹṣin (736); ìbáaka òjìlélúgba ó lé márùn-ún (245),

  12. Mordekai sì fi àṣẹ ọba Ahaswerusi kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, tiwọn yára bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba.

  13. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba tiwọn yára bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba. A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa.

  14. Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka, tí kò ní òye ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀, kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.

  15. Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ̀-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́.

  16. “ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.

  17. Bẹ́ẹ̀ ni ààrùn ẹṣin, ìbáaka, ìbákasẹ, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́.