Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Lot

34 ẹsẹ · 9 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi; nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.

  2. Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.

  3. Àwọn ọmọ Merari. Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.

  4. Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.

  5. Láti Kiṣi. Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.

  6. Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti. Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

  7. Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèké.

  8. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.

  9. Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.” Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé, “Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.” Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.