Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The High Priest Christ
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Melkisedeki ọba Salẹmu sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo.
Ó sì súre fún Abramu, wí pé, “Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.” Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
“Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.
Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.
Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.
Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”
“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé,
“ ‘ “Kí Olúwa bùkún un yín, kí ó sì pa yín mọ́.
Kí Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
Kí Olúwa bojú wò yín, kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’