Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The High Priest Christ: Aaron, &c

4 ẹsẹ · 21 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Aaron, &c

  1. “Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.

  2. Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.

  3. Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.

  4. Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”