Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Armies of Israel
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.
Nígbà náà Saulu kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.
Saulu sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Filistini lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má ṣì ṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.” Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn-ín.”
Nígbà náà ni Saulu béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Filistini lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.
Saulu sì wí pé, “Ẹ wá síyìn-ín ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí.
Bí Olúwa tí ó gba Israẹli là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jonatani ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.
Nígbà náà ni Saulu wí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jonatani ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.”
Nígbà náà ni Saulu gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jonatani àti Saulu nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.
Saulu sì wí pé, “Ẹ dìbò láàrín èmi àti Jonatani ọmọ mi.” Ìbò náà sì mú Jonatani.
Saulu sì wí fún Jonatani pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.” Jonatani sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsin yìí ṣé mo ní láti kú?”
Saulu sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, nítorí pé ìwọ Jonatani yóò sá à kú dandan.”
Dafidi sì gbọ́ ní aginjù pé Nabali ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀.
Dafidi sì rán ọmọkùnrin mẹ́wàá, Dafidi sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Karmeli, kí ẹ sì tọ Nabali lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi.
Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!
“ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ́run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ. Wò ó, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pa wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Karmeli.
Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojúrere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àsè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àti fún Dafidi ọmọ rẹ.’ ”
Nígbà tí Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba tí àwọn ọmọ Ammoni, àti Makiri ọmọ Ammieli ti Lo-Debari, àti Barsillai ará Gileadi ti Rogelimu.
Mú àwọn àkéte, àti àwọn àwo, àti ìkòkò amọ̀, àti alikama, àti ọkà barle, àti ìyẹ̀fun, àti àgbàdo díndín, àti ẹ̀wà, àti erèé, àti lẹntili.
Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàṣì màlúù, wá fún Dafidi àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ: nítorí tí wọ́n wí pé, “Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.”
Fún ọdún mẹ́ta kò sì sí ogun láàrín Aramu àti Israẹli.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, Jehoṣafati ọba Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti rí ọba Israẹli.
Ọba Israẹli sì ti wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ti wa ni Ramoti Gileadi, àwa sì dákẹ́ síbẹ̀, a kò sì gbà á padà lọ́wọ́ ọba Aramu?”
Ó sì béèrè lọ́wọ́ Jehoṣafati pé, “Ṣé ìwọ yóò bá mi lọ láti lọ bá Ramoti Gileadi jà?” Jehoṣafati sì dá ọba Israẹli lóhùn pé, “Èmi bí ìwọ, ènìyàn mi bí ènìyàn rẹ, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”
Ṣùgbọ́n Jehoṣafati sì tún wí fún ọba Israẹli pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”
Nígbà náà ni ọba Israẹli kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti Gileadi lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”