Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Affections: Carnal affections should be mortified

5 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Carnal affections should be mortified

  1. Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì ṣègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ń gbé nípa ti ara, ẹ̀yin yóò kú, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yín bá ń gbé nípa ti Ẹ̀mí, ẹ ó pa iṣẹ́ ti ara run, ẹ̀yin yóò yè.

  2. Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

  3. Ṣùgbọ́n èmi ń kó ara mi ní ìjánu, mo sì ń mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má ṣe di ẹni ìtanù fún ẹ̀bùn náà.

  4. Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà.

  5. kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run;