Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sower: Figurative

7 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Figurative

  1. Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.

  2. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

  3. báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó, nípa gbígbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo, àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.

  4. “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì. Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá. Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àjèjì ni yóò jẹ.

  5. Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

  6. Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká.

  7. Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun.