Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sower

37 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.

  2. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

  3. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè.

  4. Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀?

  5. báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó, nípa gbígbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo, àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.

  6. “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì. Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá. Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àjèjì ni yóò jẹ.

  7. Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

  8. Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé, “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀.

  9. Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́.

  10. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn.

  11. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò.

  12. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa.

  13. Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rùn-ún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn.

  14. “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.

  15. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.

  16. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde.

  17. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ.

  18. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso.

  19. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”

  20. Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”

  21. Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?”

  22. Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.

  23. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, “ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run. Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

  24. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín?

  25. Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà.