Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Simeon
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli, Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.
A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa.
Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin.
Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:
“Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ, ní àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,
tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;
ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà, àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”
Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.
Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé, “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí;
(idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
tí í ṣe ọmọ Simeoni, tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,
Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu.