Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shields

36 ẹsẹ · 23 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.

  2. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra; lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

  3. Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé, ẹ fi òróró kún asà yín!

  4. Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.

  5. “Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!

  6. “Ṣe ọfà rẹ ní mímú, mú àpáta! Olúwa ti ru ọba Media sókè, nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run. Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.

  7. Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ.

  8. “ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ. Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn.

  9. “ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárín àwọn ìlú tí ó wà ni Israẹli yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ̀—àpáta kéékèèké àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná.

  10. Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì.

  11. Ní àfikún, ẹ mú àpáta ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà.