Gilboa
32.5100, 35.4000 Wo lórí Google Maps
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Gilboa
Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa.
“Ẹ̀yin òkè Gilboa, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé, asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.
Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa.