Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shechaniah
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Àwọn ọmọ Hananiah: Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Obadiah àti ti Ṣekaniah.
Àwọn ọmọ Ṣekaniah: Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.
nínú àwọn ọmọ Ṣekaniah; nínú àwọn ọmọ Paroṣi: Sekariah, àti pé àádọ́jọ ọkùnrin fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ;
nínú àwọn ọmọ Sattu: Ṣekaniah ọmọ Jahasieli àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;
Nígbà náà ni Ṣekaniah ọmọ Jehieli, ọ̀kan lára ìran Elamu, sọ fún Esra pé, “Àwa ti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrín àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Israẹli
Lẹ́yìn wọn, Sadoku ọmọ Immeri tún ọ̀kánkán òdìkejì ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà-oòrùn ṣe àtúnṣe.
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Juda ti mulẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekaniah ọmọ Arah (Sanballati fẹ́ ọmọ Ṣekaniah), ọmọ rẹ̀ Jehohanani sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Meṣullamu ọmọ Berekiah.
Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,