Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Seventy: The senate of the Israelites composed of seventy elders

5 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The senate of the Israelites composed of seventy elders

  1. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.

  2. Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ.

  3. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú àádọ́rin ọkùnrin nínú àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrín àwọn ènìyàn wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi.

  4. Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká.

  5. Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọ̀ sánmọ̀ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́.