Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophecy: Guilt of pretending to the gift of

5 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Guilt of pretending to the gift of

  1. Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.

  2. “Láàrín àwọn wòlíì Samaria, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá. Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà.

  3. Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu, èmi ti rí ohun búburú. Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké. Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀. Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.”

  4. “Ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn wòlíì Israẹli tó ń sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn tí ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

  5. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ègbé ni fún àwọn aṣiwèrè wòlíì tó ń tẹ̀lé ẹ̀mí ara wọn tí wọn kò sì rí nǹkan kan!