Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pleasure

40 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn, ṣaworo òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

  2. Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun, pè ọ́ ní ọjọ́ náà láti sọkún kí o sì pohùnréré, kí o tu irun rẹ dànù kí o sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

  3. Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà; màlúù pípa àti àgùntàn pípa, ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu! Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu, nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”

  4. “Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

  5. Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.

  6. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá.

  7. Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó.

  8. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

  9. kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.

  10. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè.

  11. oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ.

  12. Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ òpè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sì ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé. À ń gbé ìgbé ayé àrankàn àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórìíra ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú.

  13. o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

  14. Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ, nítorí tí ó ń wo èrè náà.

  15. Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jayé nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín.