Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Months

42 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.

  2. Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.

  3. A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari tí í se oṣù kejì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi.

  4. Ní oṣù Nisani, ní ogún ọdún ìjọba ọba Artasasta, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún un, mo gbé wáìnì náà, mo fi fún ọba, ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájú rẹ̀.

  5. Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli, láàrín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta.

  6. Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú.

  7. A mú Esteri lọ síwájú ọba Ahaswerusi ní ibùgbé ọba ní oṣù kẹwàá, tí ó jẹ́ oṣù Tebeti, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀.

  8. Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari.

  9. Lẹ́sẹ̀kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù Sifani. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Mordekai sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóso baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tàdínláàádóje (127) tí ó lọ láti India títí ó fi dé Kuṣi. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn.

  10. Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun àní nígbà tí a yàn; ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.

  11. Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.

  12. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo wá, pé.

  13. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán.

  14. Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”

  15. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”

  16. Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún.

  17. ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.