Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Modern Samaria: Ready to hear and embrace the gospel

7 ẹsẹ · 23 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Ready to hear and embrace the gospel

  1. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.”

  2. Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn, ó sì dúró fún ọjọ́ méjì.

  3. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

  4. Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́, nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”

  5. Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ.

  6. Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá.

  7. Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.