Sanballat
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Sanballat
Nígbà tí Sanballati ará Horoni àti Tobiah ará a Ammoni tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnìkan wá láti mú ìtẹ̀síwájú bá àlàáfíà àwọn ará Israẹli inú bí wọn gidigidi.
Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati ará a Horoni, Tobiah ara olóyè Ammoni àti Geṣemu ará a Arabia gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé, “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?”
Nígbà tí Sanballati gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀. Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà,
Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati, Tobiah, àwọn ará Arabia, ará Ammoni, àti àwọn ènìyàn Aṣdodu gbọ́ pé àtúnṣe odi Jerusalẹmu ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi.
Nígbà tí Sanballati, Tobiah Geṣemu ará Arabia àti àwọn ọ̀tá wa tókù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́kù nínú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì ri àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà.
Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé, “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi;
Ní ìgbà karùn-ún, Sanballati rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú àpò ìwé wà ní ọwọ́ rẹ̀
Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán an, ṣùgbọ́n ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tobiah àti Sanballati ti bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀.
A! Ọlọ́run mi, rántí Tobiah àti Sanballati, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Noadiah wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbèrò láti dẹ́rùbà mí.
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Joiada, ọmọ Eliaṣibu olórí àlùfáà jẹ́ àna Sanballati ará a Horoni. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.