Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Light: Figurative and symbolic

12 ẹsẹ · 37 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Figurative and symbolic

  1. Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

  2. Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́, àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ, àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.

  3. Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé,

  4. ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.

  5. Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.

  6. Òun fúnra rẹ̀ kì í ṣe ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà.

  7. Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé.

  8. Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú.

  9. Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí.

  10. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ ní í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”

  11. Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàrín yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín, ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun ń lọ.

  12. Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn.