Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Life: From God

11 ẹsẹ · 10 abala

Àwọn ẹsẹ nípa From God

  1. “Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni! Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi. Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè. Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná, kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

  2. Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé, Èmi ti wà láààyè títí láé,

  3. Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀ tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

  4. gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀, ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.

  5. Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé; àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú. Ìwọ dá ìlera mi padà kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè.

  6. Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni, ní ti pé mo ní ìkorò ńlá. Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́, kúrò nínú ọ̀gbun ìparun; ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.

  7. Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́, ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ; àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.

  8. Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.

  9. Olúwa yóò gbà mí là bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa nínú tẹmpili ti Olúwa.

  10. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn.

  11. Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;