Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Leviathan

34 ẹsẹ · 8 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà, ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.

  2. Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ àti idẹ si bi igi híhù.

  3. Ọfà kò lè mú un sá; òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.

  4. Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko; ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.

  5. Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.

  6. Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.

  7. Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.

  8. Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀, tí a dá láìní ìbẹ̀rù.

  9. Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”