Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Journey of Israel Through The Desert

759 ẹsẹ · 177 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sọ fún Mose pé,

  2. “Kó ẹ̀yà Lefi wá, kí o sì fà wọ́n fún Aaroni àlùfáà láti máa ràn án lọ́wọ́.

  3. Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní àgọ́ ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́.

  4. Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Israẹli nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́.

  5. Fi ẹ̀yà Lefi jì Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Aaroni nínú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

  6. Olúwa tún sọ fún Mose pé,

  7. “Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi,

  8. nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

  9. Olúwa sọ fún Mose nínú aginjù Sinai ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wí pé,

  10. “Mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀.

  11. Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”

  12. Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́.

  13. Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  14. Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn.

  15. Netaneli ọmọ Suari ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Isakari;

  16. Eliabu ọmọ Heloni ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Sebuluni.

  17. Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ Gerṣoni àti Merari tó gbé àgọ́ sì gbéra.

  18. Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn.

  19. Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Simeoni.

  20. Eliasafu ọmọ Deueli ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gadi.

  21. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé.

  22. Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn.

  23. Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase.

  24. Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini.

  25. Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.