Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Hearers

23 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. “Ní tìrẹ, ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn ìlú n sọ̀rọ̀ nípa rẹ ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àti ní ẹnu-ọ̀nà ilé wọn, wọ́n ń sọ sí ara wọn wí pé, ‘Ẹ wá gbọ́ iṣẹ́ ti a ran láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá.’

  2. Àwọn ènìyàn mi wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń ṣe, wọn sì jókòó níwájú rẹ láti fetísí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mú wá sí ìṣe. Ẹnu wọn ni wọ́n fi n sọ̀rọ̀ ìfọkànsìn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn ní ìwọra èrè tí kò tọ́.

  3. Nítòótọ́ lójú wọn, ìwọ jẹ́ ẹni kan tí ó ń kọrin ìfẹ́ pẹ̀lú ohun dídára àti ohun èlò orin kíkọ, nítorí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ṣùgbọ́n wọn kò mu wá sí ìṣe.

  4. “Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta.

  5. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.

  6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn.

  7. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”

  8. Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.

  9. Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́ etí wọn sì wúwo láti gbọ́ ojú wọn ni wọ́n sì dì nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́ kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’

  10. nígbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà.

  11. Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà.

  12. Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀.

  13. Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀.

  14. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”

  15. “Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  16. Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.

  17. Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.

  18. Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó.

  19. Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.

  20. Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ.

  21. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí

  22. nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí.

  23. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.