- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Firstborn
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa.
Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́-àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà.
“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú.
Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’
Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.”
“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ìre oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ. “Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi.
Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ. Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ́ kẹjọ.
“Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i ṣe, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn.
Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo.
Olúwa sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.
Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.”
Mose sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.
Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273).
Olúwa tún sọ fún Mose pé,
“Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi. Èmi ni Olúwa.
Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Israẹli tó ju iye àwọn ọmọ Lefi lọ,
ìwọ yóò gba ṣékélì márùn-ún lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gera.
Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli tó lé yìí, ni kí o kó fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀.”
Nígbà náà ni Mose gba owó ìràpadà àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi ti ra àwọn yòókù padà.
Mose sì gba egbèje ṣékélì ó dín márùndínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli.
Mose sì kó owó ìràpadà yìí fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.
Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli.
Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Israẹli jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi.
Mo sì ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Israẹli.
Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́.