Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Damascus: Prophecies concerning

9 ẹsẹ · 12 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Prophecies concerning

  1. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku: “Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́ ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.

  2. Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀ fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀, láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.

  3. Nípa Damasku. “Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn, wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.

  4. Damasku di aláìlera, ó pẹ̀yìndà láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a; ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú, ìrora bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.

  5. Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀; ìlú tí mo dunnú sí.

  6. Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  7. “Èmi yóò fi iná sí odi Damasku, yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”

  8. Nípa ìlú Kedari àti ìjọba Hasori èyí ti Nebukadnessari ọba Babeli dojú ìjà kọ, èyí ni ohun tí Olúwa sọ, “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ ìlú Kedari, kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn run.

  9. Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn ni wọn ó kó lọ; àgọ́ wọn yóò di ìṣínípò padà pẹ̀lú gbogbo ẹrù àti ìbákasẹ wọn. Àwọn ènìyàn yóò ké sórí wọ́n pé, ‘Ẹ̀rù yí káàkiri!’