Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Creditors: Often cruel in exacting debts

13 ẹsẹ · 21 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Often cruel in exacting debts

  1. Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀sùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlú u yín! Nítorí náà mo pe àpéjọ ńlá láti bá wọn wí.

  2. Mo sì wí fún wọn pé, “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsin yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohunkóhun sọ.

  3. Nítorí náà, mo tẹ̀síwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀tá wa?

  4. Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.

  5. Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà, àwọn tálákà ayé a fi agbára sá pamọ́.

  6. Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.

  7. Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.

  8. Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.

  9. Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.

  10. Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.

  11. “Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘San gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’

  12. “Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’

  13. “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá.