Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Communion of Saints

16 ẹsẹ · 22 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.

  2. Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí, tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni: tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀.

  3. Bí ìrì Hermoni tí o sàn sórí òkè Sioni. Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún, àní ìyè láéláé.

  4. Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà.

  5. Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

  6. Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.

  7. Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn?

  8. Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?

  9. Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé: “Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàrín wọn, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

  10. Nítorí náà, “Ẹ jáde kúrò láàrín wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀, ni Olúwa wí. Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; Èmi ó sì gbà yín.”

  11. Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí.

  12. Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín.

  13. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.

  14. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye,

  15. si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé,

  16. àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ.