Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Civil Service: School for
Àwọn ẹsẹ nípa School for
Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá.
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli.
Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.
Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.
Ní òpin ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá síwájú ọba Nebukadnessari.
Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah; nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba.
Nínú gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba ń béèrè lọ́wọ́ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọ́n tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.
Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kirusi.