Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Burial: The Jews anxious to be interred in their family places of
Àwọn ẹsẹ nípa The Jews anxious to be interred in their family places of
Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Israẹli láti kú, ó pe Josẹfu, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Bí mo bá rí ojúrere ni ojú rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ejibiti.
Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Ejibiti kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.” Josẹfu sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.”
Jakọbu wí pé, “Búra fún mi,” Josẹfu sì búra fún un. Israẹli sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé orí ibùsùn rẹ̀.