Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Barnabas

32 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà.

  2. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè.

  3. Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìyìnrere náà.

  4. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi.

  5. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìyìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìyìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́.

  6. Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà.

  7. Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù.