Skip to content

Hanun

8 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Hanun

  1. Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  2. Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ammoni.

  3. Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.”

  4. Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.

  5. Dafidi rò wí pé èmi yóò fi inú rere hàn sí Hanuni ọmọ Nahaṣi, nítorí baba a rẹ̀ fi inú rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dafidi rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí Hanuni ní ti baba a rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dafidi wá sí ọ̀dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ àwọn ará Ammoni láti fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí i.

  6. Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ammoni sọ fún Hanuni pé, “Ṣé ìwọ rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nípa rírán àwọn olùtùnú sí ọ? Ṣé àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti rìn wò àti láti bì í ṣubú, àti láti ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà.”

  7. Bẹ́ẹ̀ ni Hanuni fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dafidi, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárín ìdí rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.

  8. Nígbà tí àwọn ará Ammoni sì ri pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dafidi, Hanuni àti àwọn ará Ammoni rán ẹgbẹ̀rún (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti Aramu-Naharaimu, Siria Maaka àti Soba.